Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,

Isaiah 58:13 in English

Isaiah 58:13 · Berean Standard Bible

If you turn your foot from breaking the Sabbath, from doing as you please on My holy day, if you call the Sabbath a delight, and the LORD’s holy day honorable, if you honor it by not going your own way or seeking your own pleasure or speaking idle words,

Context

11Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. 12Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́ wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀. 13“Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi, bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùn àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀ àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí, 14nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ, èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé, àti láti máa jàdídùn ìní ti Jakọbu baba rẹ.” Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.