Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi; àti ẹ̀yin tí kò ní owó; ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìdíyelé.

Isaiah 55:1 in English

Isaiah 55:1 · Berean Standard Bible

“Come, all you who are thirsty, come to the waters; and you without money, come, buy, and eat! Come, buy wine and milk without money and without cost!

Context

1“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi; àti ẹ̀yin tí kò ní owó; ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìdíyelé. 2Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn? Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu. 3Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi; gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè. Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ, ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.