Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”

Isaiah 48:20 in English

Isaiah 48:20 · Berean Standard Bible

Leave Babylon! Flee from the Chaldeans! Declare it with a shout of joy, proclaim it, let it go out to the ends of the earth, saying, “The LORD has redeemed His servant Jacob!”

Context

18Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun. 19Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn, àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.” 20Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.” 21Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú aginjù; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde. 22“Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn ìkà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.