Isaiah 44:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun tí Olúwa wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n láti inú ìyá rẹ wá, àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi, Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
Isaiah 44:2 in English
Isaiah 44:2 · Berean Standard Bible
This is the word of the LORD, your Maker, who formed you from the womb and who will help you: “Do not be afraid, O Jacob My servant, Jeshurun,* whom I have chosen.
Context
1“Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn. 2Ohun tí Olúwa wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n
láti inú ìyá rẹ wá,
àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú.
Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,
Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn. 3Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ
àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ,
Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,
àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ. 4Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.