Isaiah 43:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde, tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
Isaiah 43:8 in English
Isaiah 43:8 · Berean Standard Bible
Bring out a people who have eyes but are blind, and who have ears but are deaf.
Context
6Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé— 7ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
tí mo dá fún ògo mi,
tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.” 8Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití. 9Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́,
tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.” 10“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,
“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.