Isaiah 43:26
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi, jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀; ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
Isaiah 43:26 in English
Isaiah 43:26 · Berean Standard Bible
Remind Me, let us argue the matter together. State your case, so that you may be vindicated.
Context
24Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín. 25“Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́. 26Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,
jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;
ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn. 27Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;
àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi. 28Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún
àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.