Isaiah 43:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
Isaiah 43:2 in English
Isaiah 43:2 · Berean Standard Bible
When you pass through the waters, I will be with you; and when you go through the rivers, they will not overwhelm you. When you walk through the fire, you will not be scorched; the flames will not set you ablaze.
Context
1Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí,
ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu,
ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe. 2Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
kò ní jó ọ;
ahọ́n iná kò ní jó ọ lára. 3Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
Kuṣi àti Seba dípò rẹ. 4Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.