Isaiah 43:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
Isaiah 43:18 in English
Isaiah 43:18 · Berean Standard Bible
“Do not call to mind the former things; pay no attention to the things of old.
Context
16Èyí ni ohun tí Olúwa wí,
Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,
ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi, 17ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,
àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,
wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,
wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà: 18“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́. 19Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
Nísinsin yìí, ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá. 20Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.