Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”

Isaiah 43:15 in English

Isaiah 43:15 · Berean Standard Bible

I am the LORD, your Holy One, the Creator of Israel, and your King.”

Context

13Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?” 14Èyí ni ohun tí Olúwa wí, olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli: “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Babeli, nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. 15Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ, Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.” 16Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun, ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi, 17ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.