Isaiah 41:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí, àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.
Isaiah 41:20 in English
Isaiah 41:20 · Berean Standard Bible
so that all may see and know, may consider and understand, that the hand of the LORD has done this and the Holy One of Israel has created it.”
Context
18Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga
àti orísun omi ní àárín àfonífojì.
Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi. 19Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀
igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.
Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,
igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀ 20tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,
kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,
pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,
àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí. 21“Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí.
“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí, 22“Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa
ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,
kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn
kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí.
Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.