Isaiah 41:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù! Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe! Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀, jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.
Isaiah 41:1 in English
Isaiah 41:1 · Berean Standard Bible
“Be silent before Me, O islands,* and let the peoples renew their strength. Let them come forward and testify; let us together draw near for judgment.
Context
1“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù!
Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe!
Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀,
jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́. 2“Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá,
tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?
Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́
ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀.
Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,
láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀. 3Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà,
ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.