Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

Isaiah 40:30 in English

Isaiah 40:30 · Berean Standard Bible

Even youths grow tired and weary, and young men stumble and fall.

Context

28Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀. 29Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá. 30Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú; 31ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun. Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì; wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.