Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”

Isaiah 37:4 in English

Isaiah 37:4 · Berean Standard Bible

Perhaps the LORD your God will hear the words of the Rabshakeh, whom his master the king of Assyria has sent to defy the living God, and He will rebuke him for the words that the LORD your God has heard. Therefore lift up a prayer for the remnant that still survives.”

Context

2Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 3Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí, ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn. 4Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.” 5Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah, 6Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.