Isaiah 35:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
Isaiah 35:9 in English
Isaiah 35:9 · Berean Standard Bible
No lion will be there, and no vicious beast will go up on it. Such will not be found there, but the redeemed will walk upon it.
Context
7Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi. 8Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
a ó sì máa pè é ní ọ̀nà ìwà mímọ́.
Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá. 9Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀, 10àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.