Isaiah 35:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ní títanná yóò tanná; yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kọrin. Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un, ẹwà Karmeli àti Ṣaroni; wọn yóò rí ògo Olúwa, àti ẹwà Ọlọ́run wa.
Isaiah 35:2 in English
Isaiah 35:2 · Berean Standard Bible
It will bloom profusely and rejoice with joy and singing. The glory of Lebanon will be given to it, the splendor of Carmel and Sharon. They will see the glory of the LORD, the splendor of our God.
Context
1Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
Gẹ́gẹ́ bí ewéko, 2ní títanná yóò tanná;
yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kọrin.
Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
wọn yóò rí ògo Olúwa,
àti ẹwà Ọlọ́run wa. 3Fún ọwọ́ àìlera lókun,
mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun. 4Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé,
“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
òun yóò wá láti gbà yín là.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.