Isaiah 34:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Sioni.
Isaiah 34:8 in English
Isaiah 34:8 · Berean Standard Bible
For the LORD has a day of vengeance, a year of recompense for the cause of Zion.*
Context
6Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀
a mú un sanra fún ọ̀rá,
àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
fún ọ̀rá ìwé àgbò—
nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bosra,
àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu. 7Àti àwọn àgbáǹréré yóò
ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá,
àti àwọn ẹgbọrọ màlúù
pẹ̀lú àwọn akọ màlúù,
ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,
a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá. 8Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni,
àti ọdún ìsanpadà,
nítorí ọ̀ràn Sioni. 9Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà,
àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́,
ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná. 10A kì yóò pa á ní òru tàbí ní ọ̀sán;
èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé:
yóò dahoro láti ìran dé ìran,
kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé àti láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.