Isaiah 32:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì, gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀, àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.
Isaiah 32:2 in English
Isaiah 32:2 · Berean Standard Bible
Each will be like a shelter from the wind, a refuge from the storm, like streams of water in a dry land, like the shadow of a great rock in an arid land.
Context
1Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo
àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso. 2Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́
àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,
gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀,
àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ. 3Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,
àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀. 4Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,
àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.