Isaiah 3:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.
Isaiah 3:9 in English
Isaiah 3:9 · Berean Standard Bible
The expression on their faces testifies against them, and like Sodom they flaunt their sin; they do not conceal it. Woe to them, for they have brought disaster upon themselves.
Context
7Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,
“Èmi kò ní àtúnṣe kan.
Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé,
ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.” 8Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n
Juda ń ṣubú lọ,
ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,
láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú. 9Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,
wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu;
wọn ò fi pamọ́!
Ègbé ni fún wọn!
Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn. 10Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,
nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn. 11Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn,
a ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.