Isaiah 22:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran. Kí ni ó ń dààmú yín báyìí, tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?
Isaiah 22:1 in English
Isaiah 22:1 · Berean Standard Bible
This is the burden against the Valley of Vision: What ails you now, that you have all gone up to the rooftops,
Context
1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran.
Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,
tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ? 2Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,
ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn
a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun. 3Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;
a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.
Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,
lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà
lọ́nà jíjìn réré.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.