Isaiah 19:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.
Isaiah 19:20 in English
Isaiah 19:20 · Berean Standard Bible
It will be a sign and a witness to the LORD of Hosts in the land of Egypt. When they cry out to the LORD because of their oppressors, He will send them a savior and defender to rescue them.
Context
18Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun. 19Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. 20Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.