Isaiah 18:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú, ní àwọn ipadò Kuṣi,
Isaiah 18:1 in English
Isaiah 18:1 · Berean Standard Bible
Woe to the land of whirring wings,* along the rivers of Cush,*
Context
1Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú,
ní àwọn ipadò Kuṣi, 2tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun
lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe.
Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,
sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀,
sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,
orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè,
tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ. 3Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,
tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,
nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè,
ẹ ó rí i,
nígbà tí a bá fun fèrè kan
ẹ ó gbọ́ ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.