Isaiah 17:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá; ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
Isaiah 17:4 in English
Isaiah 17:4 · Berean Standard Bible
“In that day the splendor of Jacob will fade, and the fat of his body will waste away,
Context
2Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 3Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 4“Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;
ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù. 5Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn
irúgbìn tí ó dúró jọ
tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—
àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu. 6Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,
tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù
sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,
mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”
ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.