Isaiah 16:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu, ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
Isaiah 16:6 in English
Isaiah 16:6 · Berean Standard Bible
We have heard of Moab’s pomposity, his exceeding pride and conceit, his overflowing arrogance. But his boasting is empty.
Context
4Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”
Aninilára yóò wá sí òpin,
ìparun yóò dáwọ́ dúró;
òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀. 5Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo. 6Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. 7Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
Sọkún kí o sì banújẹ́
fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti. 8Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
èyí tí ó ti fà dé Jaseri
ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.