Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu; ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu, igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.

Isaiah 15:8 in English

Isaiah 15:8 · Berean Standard Bible

For their outcry echoes to the border of Moab. Their wailing reaches Eglaim; it is heard in Beer-elim.

Context

6Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́. 7Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari. 8Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu; ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu, igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu. 9Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni— kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.