Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari, títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi. Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ, ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.

Isaiah 15:5 in English

Isaiah 15:5 · Berean Standard Bible

My heart cries out over Moab; her fugitives flee as far as Zoar, as far as Eglath-shelishiyah.* With weeping they ascend the slope of Luhith; they lament their destruction on the road to Horonaim.

Context

3Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú. Wọ́n pohùnréré, wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún. 4Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì. 5Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari, títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi. Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ, ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn. 6Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́. 7Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.