Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún, Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.

Isaiah 15:2 in English

Isaiah 15:2 · Berean Standard Bible

Dibon goes up to its temple to weep at its high places. Moab wails over Nebo, as well as over Medeba. Every head is shaved, every beard is cut off.

Context

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu, a pa Ari run ní Moabu, òru kan ní a pa á run! A pa Kiri run ní Moabu, òru kan ní a pa á run! 2Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún, Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù. 3Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú. Wọ́n pohùnréré, wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún. 4Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.