Isaiah 13:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́ tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran; ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́, olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
Isaiah 13:20 in English
Isaiah 13:20 · Berean Standard Bible
She will never be inhabited or settled from generation to generation; no nomad will pitch his tent there, no shepherd will rest his flock there.
Context
18Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;
wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé
tàbí kí wọn síjú àánú wo àwọn ọmọdé. 19Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba
ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli
ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀
gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra. 20A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́
tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;
ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,
olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀. 21Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,
àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,
níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé
níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri. 22Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,
àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.