Isaiah 13:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì; ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
Isaiah 13:13 in English
Isaiah 13:13 · Berean Standard Bible
Therefore I will make the heavens tremble, and the earth will be shaken from its place at the wrath of the LORD of Hosts on the day of His burning anger.
Context
11Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,
àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga
èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀. 12Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn
ju ojúlówó wúrà lọ,
yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ. 13Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;
ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀
láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ. 14Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀. 15Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,
gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.