Isaiah 12:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”
Isaiah 12:2 in English
Isaiah 12:2 · Berean Standard Bible
Surely God is my salvation; I will trust and not be afraid. For the LORD GOD is my strength and my song, and He also has become my salvation.”
Context
1Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé,
“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú. 2Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
òun ti di ìgbàlà mi.” 3Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
láti inú kànga ìgbàlà. 4Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé,
“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
kí o sì kéde pé a ti gbé
orúkọ rẹ̀ ga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.