Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.

Isaiah 11:2 in English

Isaiah 11:2 · Berean Standard Bible

The Spirit of the LORD will rest on Him— the Spirit of wisdom and understanding, the Spirit of counsel and strength, the Spirit of knowledge and fear of the LORD.

Context

1Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso. 2Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa. 3Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́, 4ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.