Hosea 4:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀, wọ́n sì ti fi ara wọn
Hosea 4:10 in English
Hosea 4:10 · Berean Standard Bible
They will eat but not be satisfied; they will be promiscuous but not multiply. For they have stopped obeying the LORD.
Context
8wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi,
wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn. 9Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí.
Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn.
Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 10“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;
wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,
nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀,
wọ́n sì ti fi ara wọn 11fún àgbèrè;
wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́,
àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù. 12Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi
ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.
Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà
wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.