Hosea 3:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan.
Hosea 3:2 in English
Hosea 3:2 · Berean Standard Bible
So I bought her for fifteen shekels of silver * and a homer and a lethech of barley.*
Context
1Olúwa sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Olúwa sì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.” 2Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan. 3Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.” 4Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.