Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.

Hosea 1:9 in English

Hosea 1:9 · Berean Standard Bible

And the LORD said, “Name him Lo-ammi,* for you are not My people, and I am not your God.*

Context

7Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.” 8Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-ruhama, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni 9Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín. 10“Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ 11Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.