Native Bible

Hebrews 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i síji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.

Hebrews 9:5 in English

Hebrews 9:5 · Berean Standard Bible

Above the ark were the cherubim of glory, overshadowing the mercy seat.* But we cannot discuss these things in detail now.

Context

3Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jùlọ; 4tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú; 5àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i síji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. 6Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkígbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn. 7Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìṣìnà àwọn ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.