Heberu 9:3
Hebrews 9:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jùlọ;
Hebrews 9:3 in English
Hebrews 9:3 · Berean Standard Bible
Behind the second curtain was a room called the Most Holy Place,*
Context
1Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí. 2A gbé àgọ́ kan dìde. Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn. Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́. 3Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jùlọ; 4tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú; 5àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i síji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.