Heberu 7:24
Hebrews 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò.
Hebrews 7:24 in English
Hebrews 7:24 · Berean Standard Bible
But because Jesus lives forever, He has a permanent priesthood.
Context
22Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù. 23Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú. 24Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò. 25Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. 26Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.