Heberu 7:15
Hebrews 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki.
Hebrews 7:15 in English
Hebrews 7:15 · Berean Standard Bible
And this point is even more clear if another priest like Melchizedek appears,
Context
13Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ. 14Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mose kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà. 15Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki. 16Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin. 17Nítorí a jẹ́rìí pé:
“Ìwọ ni àlùfáà títí láé
ní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.