Heberu 3:6
Hebrews 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.
Hebrews 3:6 in English
Hebrews 3:6 · Berean Standard Bible
But Christ is faithful as the Son over God’s house. And we are His house, if we hold firmly * to our confidence and the hope of which we boast.
Context
4Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. 5Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. 6Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin. 7Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, 8ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,
bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.