Heberu 2:11
Hebrews 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá, nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin.
Hebrews 2:11 in English
Hebrews 2:11 · Berean Standard Bible
For both the One who sanctifies and those who are sanctified are of the same family. So Jesus is not ashamed to call them brothers.
Context
9Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 10Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. 11Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá, nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. 12Àti wí pé,
“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,
ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.” 13Àti pẹ̀lú,
“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”
Àti pẹ̀lú,
“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.