Native Bible

Hebrews 13:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.

Hebrews 13:9 in English

Hebrews 13:9 · Berean Standard Bible

Do not be carried away by all kinds of strange teachings, for it is good for the heart to be strengthened by grace and not by foods of no value to those devoted to them.

Context

7Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. 8Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé. 9Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè. 10Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ. 11Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si Ibi Mímọ́ Jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.