Native Bible

Hebrews 13:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si Ibi Mímọ́ Jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó.

Hebrews 13:11 in English

Hebrews 13:11 · Berean Standard Bible

Although the high priest brings the blood of animals into the Holy Place as a sacrifice for sin, the bodies are burned outside the camp.

Context

9Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè. 10Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ. 11Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si Ibi Mímọ́ Jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó. 12Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè. 13Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.