Heberu 11:24
Hebrews 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao;
Hebrews 11:24 in English
Hebrews 11:24 · Berean Standard Bible
By faith Moses, when he was grown, refused to be called the son of Pharaoh’s daughter.
Context
22Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀. 23Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Mose pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí tiwọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba. 24Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; 25o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 26Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.