Native Bible

Habakkuk 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

Habakkuk 3:6 in English

Habakkuk 3:6 · Berean Standard Bible

He stood and measured the earth; He looked and startled the nations; the ancient mountains crumbled; the perpetual hills collapsed. His ways are everlasting.

Context

4Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí. 5Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ; ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ. 6Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni. 7Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora. 8Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn odò nì, Olúwa? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun tí ìwọ fi ń gun ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.