Gẹnẹsisi 8:6
Genesis 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.
Genesis 8:6 in English
Genesis 8:6 · Berean Standard Bible
After forty days Noah opened the window he had made in the ark
Context
4Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. 5Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn. 6Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀. 7Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀. 8Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.