Native Bible

Genesis 8:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró.

Genesis 8:2 in English

Genesis 8:2 · Berean Standard Bible

The springs of the deep and the floodgates of the heavens were closed, and the rain from the sky was restrained.

Context

1Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. 2Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. 3Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. 4Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.