Gẹnẹsisi 8:18
Genesis 8:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde.
Genesis 8:18 in English
Genesis 8:18 · Berean Standard Bible
So Noah came out, along with his sons and his wife and his sons’ wives.
Context
16“Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. 17Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.” 18Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde. 19Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn. 20Noa sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.