Gẹnẹsisi 8:12
Genesis 8:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.
Genesis 8:12 in English
Genesis 8:12 · Berean Standard Bible
And Noah waited seven more days and sent out the dove again, but this time she did not return to him.
Context
10Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. 11Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 12Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. 13Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. 14Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.