Gẹnẹsisi 8:11
Genesis 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.
Genesis 8:11 in English
Genesis 8:11 · Berean Standard Bible
And behold, the dove returned to him in the evening with a freshly plucked olive leaf in her beak. So Noah knew that the waters had receded from the earth.
Context
9Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. 10Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. 11Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. 12Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. 13Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.