Native Bible

Genesis 6:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya.

Genesis 6:2 in English

Genesis 6:2 · Berean Standard Bible

the sons of God saw that the daughters of men were beautiful, and they took as wives whomever they chose.

Context

1Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. 2Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. 3Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.” 4Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.