Native Bible

Genesis 5:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan.

Genesis 5:28 in English

Genesis 5:28 · Berean Standard Bible

When Lamech was 182 years old, he had a son.

Context

26Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 27Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú. 28Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan. 29Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.” 30Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.